Ọmọ carpenter to di rapper
Láti workshop sí microphone
Mo fi sawdust kọ́ ìtàn ayé mi
Mo fi struggle kọ́ orin mi
Ìbàdàn ló bí mi
Ìgboro ló dá mi
Hammer wà lọ́wọ́ mi tẹ́lẹ̀
Báyìí microphone ló wà lọ́wọ́ mi
Mo ti gé plank
Mo ti gbe plywood
Mo ti ṣiṣẹ́ láti òwúrọ̀ títí di alẹ́
Kí n lè rí owó jẹun
Ọ̀pọ̀ sọ pé rap ò ní gbé mi débi kankan
Ọ̀pọ̀ sọ pé dream mi pọ̀ ju reality lọ
Ṣùgbọ́n mo mọ ibi tí mo ń lọ
Mo mọ ohun tí mo ń wá
Nínú erùpẹ̀ mo ti ṣiṣẹ́
Nínú oòrùn mo ti ṣiṣẹ́
Nínú ebi mo ti ṣiṣẹ́
Nínú wahala mo ṣi ń rẹ́rìn-ín
Ọmọ carpenter mi ò bẹ̀rù iṣẹ́
Nítorí iṣẹ́ ni o kọ́ mi discipline
Iṣẹ́ ni o kọ́ mi patience
Iṣẹ́ ni o kọ́ mi bí mo ṣe lè survive
Mo rí àwọn tó ń flex lórí internet
Mo rí àwọn tó ń fake lifestyle
Ṣùgbọ́n mi ò fẹ́ fake glory
Mi ò fẹ́ borrowed success
Mo fẹ́ blessing tó mọ́
Mo fẹ́ glory tó pé
Mo fẹ́ success tí mo ṣiṣẹ́ fún
Kí n lè sọ pé "èmi ni mo jà fún un"
Ọ̀pọ̀ ọjọ́ ni pocket mi dry
Ọ̀pọ̀ ọjọ́ ni transport ò sí
Ṣùgbọ́n mi ò fi dream mi ṣeré
Nítorí mo mọ̀ pé ọjọ́ mi ń bọ̀
Láti carpenter dé rapper
Láti workshop dé stage
Láti hardship dé happiness
Láti struggle dé success
Tí o bá rí mi lónìí
Má wo ibi tí mo wà nìkan
Wo ibi tí mo ti ń bọ̀
Nítorí ibẹ̀ ni agbára ìtàn mi wà
Ọmọ carpenter to di rapper
Kò sí shortcut nínú ìtàn mi
Na sweat, prayer àti hustle
Lo kọ orúkọ Badaman sílẹ̀
Ọjọ́ kan mo máa shine bí morning sun
Kì í ṣe bí bulb tó low
Ọjọ́ kan gbogbo ìgboro máa sọ
"Ọmọ carpenter náà ti blow." 🔥🎤🥷
Yankee badaman