ẸKÙN WỌ RAP – ÌBÍLẸ̀
( intro
(Talking Drum Call)
(Talking drum + backup chant)
Lead:
Ọmọ ẹkùn wọ rap…
Backup
Badaman
aaaaa oo
Lead:
Ọmọ ẹkùn wọ rap…
Backup:
Gbogbo eranko ma pa lọ̀lọ̀
Lead:
Badaman… ọmọ ekun…
Backup:
Roar! Roar
Ọmọ ẹkùn wọ rap, ilẹ̀ gbón bí ìlù bàtá,
Nígbà tí ẹkùn wọ igbo, gbogbo eranko dáa sáká.
Bí ẹkùn bá ké — ramu ramu, Gbogbo Igbo àpà lọ̀lọ̀
Gbogbo ọmọ eranko mọ̀ pé ọba dé won ma fọ̀
Badaman
Ọmọ ẹkùn nada, ọmọ ẹkùn nare,
Ọmọ ẹkùn ìbílẹ̀ tí kò mọ ìbẹ̀rù nínú igbo rere.
(Verse)
Omo Badaman
Ojú mi ẹkùn, ìdúró mi ẹkùn,
Ọ̀rọ̀ mi jin bí ìsàlẹ̀ odò tí kò lórí ìkùn.
Ọ̀rọ̀ tí mo sọ kì í ṣeré, bí àrá tó ń kọ lu òkè,
Tí mo bá gbé ohùn mi sókè, gbogbo eranko tio laya afi ereke
Fo’óbú sí mi, kí orí ija ẹkùn
mo'n fẹ kémọ̀ pé Ẹ-kùn kì í sáré fún eranko kékeré toba binu
Ọmọ ọdẹ nínú ẹ̀mí , jagunjagun nínú ẹ̀jẹ̀,
Ìran baba baba mi ni ń jà ogun kiriji kìṣe ẹ̀fẹ̀
Ìkìlọ̀ (Hook / Chorus)
Ọmọ ẹkùn wọ rap — igbo yí padà,
Bí ẹkùn bá ké, gbogbo eranko dáa sáká.
Ọmọ ẹkùn wọ rap — ìlù gbọ́ ìró,
Ẹ-kùn kì í bẹ̀rù nínú igbo toro
(Verse 2)
Awon baba baba mi, tí ogun bá dé,
Ẹkùn ni wọ́n Yi ra pada si jagunjagun dé.
Ẹkùn kì í ṣọ́ọ̀jà, ẹkùn kì í ṣeré,
Ọba ni nínú igbo, gbogbo eranko mọ̀ pé.
Ẹkùn kì í bẹ̀rù nínú igbó pẹ̀lú ìkùn rẹ̀,
Agbára inú towa Laarẹ̀ lo ń jẹ́ kó dúró lórí ilẹ̀ rẹ̀.
Ọ̀rọ̀ mi dàbí ìlù Ogun tí ń dun láti òkè,
Tí mo bá wọ industry, gbogbo street ló ń ma gbón rapper tuntun dè
(Afárá (Bridge)
Ọmọ ẹkùn… ọmọ igbo…
Kiniun tí ń rìn láì bẹ̀rù ogun.
Ọmọ ẹkùn… ọmọ ìbílẹ̀…
Agbára ilẹ̀ ló ń gbé e soke.
(Hook / Chorus)
Ọmọ ẹkùn wọ rap — igbo yí padà,
Bí ẹkùn bá ké, gbogbo eranko dáa sáká.
Ọmọ ẹkùn wọ rap — ìlù gbọ́ ìró,
Ẹ-kùn kì í bẹ̀rù nínú igbo toro
(verse 3)
No fear in the heart when the warrior show.
My rap be roar, my bars be claw,
When Badaman talk everybody pause.
Ibile code inside every rhyme,
Ancient drum rhythm beating with time.
Talking drum call, ancestors hear,
When tiger step forward no creature come near.
(Outro)
Ọmọ ẹkùn wọ rap — jung